print-logo2
A+ A-

Ihinrere Jesu | Gospel in Yoruba

pdf

Irohin Ihinrere

–  Jowo ka eyi:

Gen 1:1 Li atetekose Olorun da orun oun aye.
Romu 3:23 Gbogbo eniyan sa li o sa ti se ti won ti kuna ogo Olorun.
Johanu 8:34 Jesu da won lohun pe, looto ni mo wi fun yin, enikeni ti o ba n dese, ouun li eru ese.

Olorun daw a sugbon a ko mo asi yapa kuro lodo re nitori iseda ese wa. Igbe aye wa laisi Olorun ko ni itumo ati ojutu. Atubotan (idiyele lati san) ese wa ni iku ni tie mi ati ara. Iku emi tumo si iyapa kuro lodo Olorun. Iku ti ara ni idibaje ara. Bi a ba ku ninu ese wa ao yawa nipa laelae kuro lodo Olorun ao si pari si inu ina. Bawo ni a se le gba ara wa kuro ninu ese ki a si pada sodo Olorun? A ko le gba ara wa nitori ko sese fun elese lati gba ara re la (bi eni ti o n ri somi ko se le gba ara re la). Yala ni awon elomiran le gba wa la nitori elese ni gbogbo wa (eni ti o n ri ko le gba elomiran ti o n ri la). A nilo eni ti ko lese ( ti ko ri) lati gba wa ninu ese. Alailese nikan ni o le gba wa. Bawo ni a se le ri alailese eniyan ninu aye ese yii nibi ti gbogbo eniyan ti dese?

Romu 6:23 Nitori iku li ere ese sugbon ebun ofe Olorun ni iye ti ko nipekun ninu Kristi Jesu oluwa.
Johanu 3:16 Nitori Olorun fe araye tobe ge ti o fi omo bibi re kan soso funni, pe enikeni ti o ba gbagbo ma ba segbe sugbon, ki o le ni iye ainipekun.
Mati 1:23 “Kiyesi, wundia kan yoo loyun, yi o si bi omo okunrin kan, won maa pe oruko re ni Emmanueli itumo eyi ti ise, “Olorun wa pelu wa.”
Johanu 8:23 O si wi fun won pe, “eyin ti isale wa; Emi ti oke wa. Eyin je ti aye yi; Emi kii se ti aye yi.
Maku 1:11 Ohun kan si ti orun wa, wipe, “Iwo ni ayanfe omo mi, eni ti inu mi dun si gidigidi.”
Johanu 8:36 Nitori naa bi omo ba so yin di ominira, e o di ominira nitooto.
Johanu 3:3 Jesu dahun o si wi fun pe, “Looto looto ni mo wi fun o, bikose pe a tun eniyan bi, oun kole ri ijoba Olorun.”
Johanu 1:12 Sugbon iye awon ti o gba, awon li o fi agbara fun lati di omo Olorun, ani awon naa ti o gba oruko re gbo:

Olorun, eni ti o dawa ti o si feran wa gidigidi, fun wa ni ona abayo. Ninu ife ijinle re fun wa o ran omo re, Jesu,lati ku fun ese wa. Jesu ko lese nitori kii se ti aye, ati, nigba ti o wa ninu aye, o bori adanwo esu lati dese. Igbe aye re wu Olorun l’orun. Jesu rue se wa o si ku lori agbelebu fun ese wa. Oun ni olugbala aye wa (Jesu le gba wa nitori pe ko ri). Idi ti Jesu fi ku lori agbelebu ni lati san idiyele ese wa ati lati mu ese wa kuro ki o si se atunse ibasepo wa pelu Olorun. Awa laaye ninu iku emi (iyipada kuro lodo Olorun) nipase agbara Olorun. Ibasepo tuntun yii ni a n pe ni atunbi. Eyi dawa pada si idi iseda ati iwa laaye wa ati, osi fun wa ni itumo ati idi fun iwa laaye.

Johanu 11:25 Jesu wi fun pe, “Emi ni ajinde ati iye. Eni ti o ba gba mi gbo, bi o tile ku, yi o ye.
Romu 6:9 Nitori awa mope bi a ti ji Kristi dide ninu oku, ko n ii ku mo; iku ko ni ipa lori re mo.
Ise 2:24 Eni ti Olorun gbe dide, nigba ti o titu irora iku; nitori ti ko se ise fun un lati dii mu.
Rom 14:9 Nitori idi eyi naa ni Kristi se ku, ti o sit un ye,ki o le je Oluwa ati oku ati alaaye..
Ise 1:11 Ti won si wi pe, eniyan ara Galili, ese ti e fi duro ti e n wo oju orun? Jesu naa yii, ti a gba soke orun kuro lowo yin, yoo pada bee gege bi e ti rii ti o n lo si orun.

Kini eri pe irubo iku Jesu fun ese wa se itewogba lodo Olorun ni orun? Eri naa ni ajinde Jesu ni iku lowo Olorun. Nipa ajinde,o fihan pe Jesu ti segun iku (tabi, ni oro kan, iku ko ni agbara lori re). Bayi, nitori naa, nitori Jesu wa laaye, a le wa laaye pelu. Iye re ninu wa fun wa ni iye. Bakan naa, nitori o jinde, o wa laaye loni.

John 5:24 “looto, looto ni mo wi fun yin, enikeni ti o ba gbo oro mi ti o ba si gba eni ti o ranmi gbo, o ni iye ti ko nipekun, oun ki yio si wa si idajo, sugbon o ti re iku koja bo si iye.
John 10:9 Emi ni ilekun,bi enikeni ba ba odo mi wole, oun li a o gba la, yio wole, yio si jade, yio si ri koriko.
John 14:6 Jesu wi fun pe, emi li ona ati otito ati iye;ko si enikeni ti o le wa sodo baba bikose nipase mi.
John 8:24 Nitori naa ni mo se wi fun yin pe, e o ku ninu ese yin, nitori bikose ba gbagbo pee mi ni e o ku ninu ese yin.”
Acts 4:12 Ko si si igbala lodo elomiran, nitori ko si oruko miran labe orun ti a fifunni ninu eniyan,nipa eyiti a le fi gba wa la.”
Rom 10:13 Nitori enikeni ti o bas a pe oruko Oluwa, li a o gbala.
Rom 10:11 Nitori iwe mimo wi pe, enikeni ti o ba gba a gbo oju ki yi o tii.
Rom 2:11 Nitori ojusaju eniyan ko si lodo Olorun.
Rom 3:22 Ani ododo Olorun nipa igbagbo ninu Jesu Kristi si gbogbo eniyan, ati lara gbogbo awon ti o gbagbo; nitori ti ko si iyato.;
Rom 10:9 Pe, bi iwo ba fi enu re jewo Jesu li oluwa, ti iwo si gbagbo li okan re pe, Olorun j ii dide kuro ninu oku, a o gba o la.

Bawo ni a se le mu ese wakuro ati lati gba aye tuntun yii? Nipa igbagbo ninu Jesu gege bi oluwa ati olugbala. Bi a ba ronupiwada igbe aye ese wa ti a sip e Jesu lati dariji ati gba wa, yi o se. Jesu je omo Olorun ti o was aye lati ku fun awon ese wa. Enikeni ninu aye ti o ba gbekele yoo gba idariji ese lodo Olorun, yoo di eni igbala lowo ese (ati ina) yi o si gba aye tuntun lodo Olorun. Olorun kii se ojusaju. Kii wo- agbegbe ti a n gbe, ede ti a n so, olowo tabi otosi, okunrin tabi obinrin, omode tabi agba, tabi awon orisii ohun afojuri miiran. Eni ti o ba gbagbo ti o si jewo Jesu yoo deni igbala. Eyi je adura ti o le gba bi o ba pinu lati tele Jesu:

Olorun ni orun,mo dupe pe o ran omo re kan soso, Jesu, lati ku fun ese mi ki n le di eni igbala ki n si ni igbe aye tuntun lati orun. Mo ronupiwada ona mi mo si beerre fun idariji ese mi. Mo gba Jesu gbo, mo si gba Jesu ni Oluwa ati olugbala mi. Ranmi lowo ki o si tomi lati gbe igbe aye ti o te o lorun ninu igbe aye otun yii ti o fun mi. Amin

Bi o ba ti gba adura oke yii, so fun Olorun lati fi ijo ti wa maa lo han o. Ba Olorun soro ninu adura nigba gbogbo Olorun yoo sib a o soro. Teti si ohun Olorun. Olorun yoo to o. O feran re yoo si toju re. O le gbekele. Kii ja awon ti o gbekele kale. Olorun je olorun ti o dara. O see gbekele. O le gbekele fun igbe aye re. Mu aini re towa. Yoo se itoju re yoo si bukun fun o. Olorun wi pe, ‘Emi kii yo fi o sile tabi ko o’. Ni igbekele ninu Olorun. Di alabukun nipase Jesu.

Ka bibeli deedee, bere lati inu iwe Johanu. Fun ekunrere ohun elo lori ayelujara, Te ibi.